Aller au contenu principal

Eku Edewor


Eku Edewor


Georgina Chloe Eku Edewor-Thorley, tí a mọ̀ sí Eku Edewor (ọjọ́ìbí: 18 Oṣù Kejìlá, Ọdún 1986), jẹ́ òṣèrébìnrin, atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù àti afẹwàṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì. Ó gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù kan táa pè ní 53 Extra, èyí tí ó maá n jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ lóri ìkànnì Africa Magic .

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

Wọ́n bí Edewor àti ìkejì rẹ̀ Kessiana ní Ilé-ìwòsàn Portland ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù. Ìyá rẹ̀ tí n ṣe Juliana Edewor jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà. Bàbá rẹ̀ náà tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Hugh Thorley, jẹ́ ará Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sí. Àwọn òbí Edewor kọrawọn sílẹ̀ nígbàtí ó wà lọ́mọdé, àwọn méjèjì sì tún ìgbeyàwó ṣe pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ọkọ tí ìyá rẹ̀ padà fẹ́ ti di olóògbé.

Edewor dàgbà ní Nàìjíríà àti Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì. Ó gbé ní ìlú Èkó títí ó fi pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, níbi tí ó ti ní ètò-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti ilé-ìwé St. Saviour's School àti ilé-ìwé Grange School. Lẹ́hìn náà Edewor padà sí Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì, níbi tí ó ti lọ sí ilé-ìwé Benenden School for Girls.

Edewor gba oyè-ẹ̀kọ́ ní ọdún 2008 nínu ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti eré ìtàgé láti Warwick University tó wà ní ìlú Coventry. Lẹ́hìn náà, ó kẹ́kọ̀ọ́ eré fíìmù ṣíṣe fún oṣù mẹ́ta ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York Film Academy ní ọdún 2009.

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

Edward kọ́kọ́ ṣàfihàn nínu tẹlifíṣọ̀nù ní ọdún 2006 nígbà tí ó fi díje níbi Britain’s Next Top Model. Ó kópa nínu àwọn sinimá àgbéléwò ní àkókó ìgbà tí ó n kàwé lọ́wọ́.Ó kópa nínu fíìmù ọdún 2010 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sex & Drugs & Rock & Roll.

Àwọn ìtọ́kasí


Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Eku Edewor by Wikipedia (Historical)


INVESTIGATION