Aller au contenu principal

Ìdìbò Gbogbogbòò Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà ti Ọdún 2023


Ìdìbò Gbogbogbòò Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà ti Ọdún 2023


Ìdìbò Gbogbogbòò Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà tí Ọdún 2023 wáyé ní ọjọ́ karúndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2023 láti dìbò yan Ààrẹ, Ìgbàkejì ààrẹ, àwọn aṣojú ilé ìgbìmò asofin àgbà àti ilé ìgbìmò asofin kékeré ní Nàìjíríà. Ààrẹ Nàìjíríà lọ́wọ́ lọ́wọ́, ààrẹ Muhammadu Buhari kò le du ipò ààrẹ mọ́, lẹ́yìn tí ó ti lo ṣáà méjì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà.

Ètò Ìdìbọ̀

Ìdìbò Ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà ma ún jẹ́ gbèdéke méjì. Láti yege ní gbèdéke àkọ́kọ́, olùdíje gbọ́dọ̀ ní ó kéré jù, ìdásí-mẹ́rin ìbò ní ìpínlẹ̀ mẹ́rinlélógún nínú Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì Nàìjíríà. Tí olùdíjé kankan kò bá yege ní gbèdéke àkọ́kọ́ yìí tàbí tí olùdíjé tó yege bá ju ẹyọ kan lọ, gbèdéke kejì ma dá lórí olùdíjé tí ó bá ní ìbò jù nínú àwọn Ìpínlẹ̀ Nàìjíríà.

Ààyè mọ́kàndínládọ̀fà ni ó wà fún ipò ilé ìgbìmò asofin àgbà ti (aṣojú mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ kọ̀kan pẹ̀lú aṣojú mẹ́fà ní Federal Capital Territory). Ipò ọ́ta lélọ́ọ̀dúnrún ni ó wà fún ipò Ilé ìgbìmò asofin kékeré Nàìjíríà.

Ìdìbọ̀ sípò ààrẹ

Ìbò abélé ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress

Ààrẹ Muhammadu Buhari kò le du ipò ààrẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti lo ṣáà méjì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà. Ìdìbọ̀ abélé ẹgbẹ́ òsèlú APC wáyé ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 2022 ní Abuja, Bola Ahmed Tinubu, gomina Ìpínlẹ̀ Èkó télèrí sì ló jáwé olúborí. Ní àárín oṣù kẹfà, ẹgbẹ́ òsèlú APC fi orúkọ Kabir Ibrahim Masari kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adi ilé mú ìgbà kejì ààrẹ kí wọ́n tó yan ààrẹ kí wọ́n tó yàn ẹni tí yó jẹ́ olùdíje ígbákejì ààrẹ fún ègbé náà. Ní ọjọ́ Kẹ̀wá oṣù keje, Ibrahim Masari fi ipò náà kalẹ̀, ní ọjọ́ kan náà, Tinubu yan Kashim Shettima—aṣojú ilé ìgbìmò asòfin àgbà fún Borno Central àti Gómìnà télèrí ìpínlè Borno—gẹ́gẹ́ bi olùrọ́pò rẹ̀.

Ìdìbọ̀ abẹ́lẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party

Ní ọjọ́ ogbọ̀n oṣù Kàrún ọdún 2022, ìgbà díè lẹ́yìn tí Gómìnà ìpínlè Anambra tẹ́lẹ̀ rí, Peter Obi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú náà láti ẹgbẹ́ òsèlú PDP, ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party se Ìdìbọ̀ abẹ́lẹ́ ní Asaba níbíntí wón ti yan Peter Obi . Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹfà, ẹgbẹ́ òsèlú náà fi orúkọ Doyin Okupe(onímọ̀ ìsègùn àti ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú PDP télèrí) gẹ́gẹ́ bi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a di ilé mú ipò olùdíje ipò ígbákejì ààrẹ lábé ẹgbẹ́ òsèlú náà. Ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 2022, Okupe fi ipò náà sílè, Obi sì kéde Yusuf Datti Baba-Ahmed—Senato télèrí láti àríwá Kaduna—gẹ́gẹ́ bi ìrọ́pọ̀ rẹ̀.

Ìdìbò abélé ẹgbẹ́ òsèlú New Nigeria Peoples Party

Ìdìbò abélé ẹgbẹ́ òsèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP) wáyé ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdun 2022, Rabiu Kwankwaso, sì ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bi olùdíje fún ipò ààrẹ lábé ẹgbẹ́ òsèlú náà. Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù keje ọdún 2022, Kwankwaso yan Isaac Idahosa gẹ́gẹ́ bi amúgbá lẹ́gbẹ̀ rẹ̀ nínú Ìdìbọ̀ náà.

Ègbé òsèlú People's Democratic Party

Ní ọjọ́ kejidinlogbon oṣù Kàrún ọdún 2021, Ìdìbọ̀ abẹ́lé wáyé ní Abuja, wón sì yan Atiku Abubakar. Ní ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù kẹfà, Abubakar yan Gómìnà ìpínlè Delta, Ifeanyi Okowa gẹ́gẹ́ bi amúgbá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Ìdìbọ̀ sípò ilé ìgbìmò asofin

Ìdìbò sípò ilé ìgbìmò asofin àgbà

Ayé okandinladofa(109) ilé ìgbìmò asofin àgbà ma sí sílè fún ìbò

Ìdìbọ̀ sípò ilé ìgbìmò asofin kékeré

Ayé ọ́ta lélọ́ọ̀dúnrún(360) ilé ìgbìmò asofin kékeré ma sí sílè fún ìbò

Àbájáde ìdìbò

Bola Ahmed Tinubu ni ó jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọdun 2023

Àwọn Ìtókasí

Giuseppe Zanotti Luxury Sneakers

Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Ìdìbò Gbogbogbòò Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà ti Ọdún 2023 by Wikipedia (Historical)


ghbass