Aller au contenu principal

Taye Taiwo


Taye Taiwo


Taye Ismaila Taiwo  jẹ́ àgbá Bọ́ọ̀lù ọmo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó gbá bọ́ọ̀lù owó ẹ̀yìn fún orílè-èdè Nàìjíríà àti fún ẹgbẹ́ àgbágbọ́ọ̀lù RoPí. Wọ́n bi ní ọjọ́ kẹrin dínlógún oṣù kẹrin(April 16) ọdún 1985.

Iṣẹ́ rẹ̀ ní àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù

Lobi Stars

Lẹ́yìn tí ó ti lo ọdún kan nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà Division 1 ní  Gabros International. Wọ́n ra Taiwo wá si ìpele Nigeria Premier League, sínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Lobi Stars. Níbi tí ó tún  ti lo ọdún kan .

Olympique de Marseille

Ní ọdún 2005, nígbà tí ó pé ọmọ ogún ọdún, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Faranse kan ti o n je Olympique de Marseille gba Taiwo sinu iko won. Won ra Taiwo lati le ropo ogbeni Bixente Lizarazu ti o ti lo sinu egbe agbaboolu  Bayern Munich. Taiwo lo gba boolu ti iko re Olympic Marseille fi jawe olubori fun iko agbaboolu Olympique Lyonnais ni 21 March 2010, pelu ese osi re lati ona to jin. Otun gba boolu sinu awon egbe agbaboolu  US Boulogne ti o tun je ki iko Olympic Marseille o jawe olubori ni 17 April 2010. Ni ojo  23 April 2011, Taiwo naa lo tun se sababi ti egbe agbaboolu re fi jawe olubori ninu ifese-wonse to waye laari iko re pelu iko agbaboolu Montpellier HSC pelu ami ayo kan soso ni ori papa Stade de France  ti o si je ki egbe agbaboolu re o gbe ife eye  2011 Coupe de la Ligue. Leyin idije yii, Taiwo mu ero gbohun-gbohun lati fi idunnu re han pelu awon ololufe egbe agbabooolu re ni eyi ti o ku die ki won fun ni iwe gbele re fun odun kan lati owo ajo  LFP. Sibe, Taiwo si gba iwe gbele re fun ifese-wonse kan fun ohun ti o se naa ti o si padanu lati kopa ninu ifese-wonse ti o keyin Liigi naa, sugbon o bebe .  Bi o se wu Taiwo lati wa pelu egbe agbaboolu Marseille, o kede re  lati fi egbe agba-boolu naa sile lopin odun naa Ti oun yoo si po soke raja ni opin odun 2010-11.

Milan

Ni May 9, 2011. Akoni moogba egbe agba-boolu  A.C. Milan iyen Massimiliano Allegri, fi onte luu pe ki Taiwo o dara po mo iko re ti yoo si je amugba-legbe fun agba-boolu omo ile Faranse kan ti o n je Philippe Mexès. O ye ki awon mejeji o jo gba boolu papo fun iko won ni odun 2011–12. Sugbon ninu idije akoko re ni o ti gba boolu kan si awon ti iko re AC Millan fi na iko agba-boolu Cesena ti o wa nile ni ami eyokan si oodo 1-0 ni 24 September 2011. Ni kete ti o gba gba boolu naa wole ni won fi Luca Antonini  ropo re. Ni December 2011, Taiwo foro jomi toro oro pelu iwe iroyin ile Faranse kan L'Équipe ni bi ti o ti fi edun okan re han si bi inu re ko se dun si ohun ti oju re n ri ninu egbe agba-boolu re A.C. Milan, paa paa julo eyi ti o n ri lara akoni moogba re Massimiliano Allegri pelu bi ko se loo mo ninu awon ifese-wonse to tun waye. Taiwo kabamo wipe oun i ba duro sinu egbe agba--boolu ile Italy ti oun wa tele ju bi oun n fidi rale lori aga ipaaro lasan lo .

Queens Park Rangers

Ni  24 January 2012, Queens Park Rangers gba Taiwo wole sinu iko won lati inu egbe agba-boolu AC Milan pelu eyawo titi di opin odun naa, pelu alakale wipe awon yoo ra Taiwo ni Milionu meta ole maruun £3.5 M. Leyin ti won ti se igbese lori  QPR, Taiwo ni oun gbero lati mu ilapa ire wo egbe agba-boolu tun tun naa ju ki oun o ma joko lori aga ipaaro lasan lo. O tun ja fita  fita ni 1 February nigba ti iko re ba iko  Aston Villa pade ni  Birmingham, ninu ifese-wonse ti o pari si eji eji 2–2. Taiwo pinu wipe oun yoo duro si inu egbe agba-boolu Queens Park Rangers. O gba boolu akoko re sinu awon pelu Free kick ti o to iwon ese bata metadin-logbon 27 yards ti won si lu iko Sunderland pelu ami ayo meta si okan 3-1 ni 24 March 2012.

Dynamo Kyiv

Ni 31 July 2012, Taiwo dara po mo egbe agba-boolu ile  Ukrainian kan Dynamo Kyiv pelu yiya ofe, pelu alakale wipe won yoo ra lopin odun naa.

Bursaspor

Ni  5 July 2013, Taiwo tun kowo bowe lati gba boolu fun egbe agba-boolu ile  Turkey kan Bursaspor fun odun meta Egba agba-boolu  Cardiff City fe kowo le lati le mu lo si idije Premier Legue, sugbon o pinu lati ba egbe agba-boolu ile Turkey naa lo. Ni 1 August 2013, Taiwo gba boolu ti o je ki iko re gba omi 2-2 draw pelu iko Vojvodina ninu iffese-wonse akoko  Europa League. Ni 27 April 2015, Taiwo gba lati fopin si ibasepo re pelu iko re Bursaspor.

HJK

Ni 23 August 2015, Taiwo dara po mo egbe gba-boolu  HJK ti odun na fi pari ti o si tun lo odun kan si pelu won. Ni osu October odun kan naa, HJK gba Taiwo wole fun  idije ti odun  2016. .

Lausanne-Sport

Ni 30 January 2017, Taiwo dara po mo Lausanne titi di opin odun 2016/17.

AFC Eskilstuna

Taye Taiwo tun dara po mo  Allsvenskan , AFC Eskilstuna fun ipari idije  August odun 2017.

Alaye lori awon egbe agba-boolu re to ti dara po mo

Egbe agba-boolu

1 Includes Trophée des champions

International

Statistics accurate as of match played 29 February 2012

International goals

Awon ife to ti gba

Egbe agba-boolu

Marseille
  • Ligue 1: 2009–10
  • Coupe de la Ligue: 2010, 2011
  • Trophée des Champions: 2010
  • UEFA Intertoto Cup: 2005
Milan
  • Supercoppa Italiana: 2011

Individual

  • 2005 FIFA World Youth Championship silver medal
  • 2005 FIFA World Youth Championship bronze ball
  • Confederation of African Football Young Player of the Year: 2006
  • Ligue 1 Team of the Year: 2008, 2009, 2011
  • Africa Cup of Nations: Team of all Tournaments

Awon itoka si

Awon ijapo ita

  • Taye Taiwo - FIFA competition record

Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Taye Taiwo by Wikipedia (Historical)