Aller au contenu principal





Text submitted to CC-BY-SA license. Source: by Wikipedia (Historical)






Text submitted to CC-BY-SA license. Source: by Wikipedia (Historical)


Ahmed Senoussi


Ahmed Senoussi


Ahmed Senoussi (ti a bi ni Oṣu Kini Ọjọ 22, Ọdun 1946) jẹ olufo giga ti orilẹ-ede Chad tẹlẹ.

O pari ni ipo kejila ni ipari fifo giga ni ere Olimpiiki 1968 . O tun dije ninu ere Olimpiiki 1972 laisi dey ipari.

Awọn itọkasi

Ita ìjápọ

  • IAAF profile for Ahmed Senoussi
  • Ahmed Senoussi at the International Olympic Committee
  • Ahmed Senoussi at Olympics.com
  • Ahmed Senoussi at Olympics at Sports-Reference.com (archived)

Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Ahmed Senoussi by Wikipedia (Historical)


Moses Bliss (akọrin)


Moses Bliss (akọrin)


Moses Bliss Uyoh Enang, tí gbogbo ènìyàn mọ sí Moses Bliss (tí a bí ní oṣù kejì ọjọ́ ogún ọdún 1995), jẹ́ akọrin ìhìnrere Nàìjíríà, adarí orin àti Ònkọ̀wé orin. Ó tún jẹ́ òlùdásílẹ̀ "Spotlite Nation", aami akọọlẹ Nàìjíríà. Moses Bliss kọ́kọ́ ṣe ifilọlẹ akọkọ rẹ ní Oṣù Kìíní ọdún 2017 tí àkọlé jẹ́ “E No Dey Fall My Hand” tí ó sì dìde ní òkìkí pẹ̀lú orin tí o kọlù “Tóò faithful” tí o gbé jáde ní oṣù karùn-ún ọdún 2019. Ní ọdún 2020, ó gbé gba ó ròkè ní Loveworld International Music and Arts Eye (LIMA 2020) nípasẹ̀ Chris Oyakhilome fún orin rẹ “Iwọ Mo N gbe fun”.

Iṣẹ́ orin

Moses Bliss bẹ̀rẹ̀ sí nifẹ sí orin nígbà ewé rẹ. Láti ọmọ ọdún márùn-ún, ní o tí kọ́ àti bí ó tí lù àwọn irinse orin. Lẹ́yìn náà, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ní ìjọ onígbàgbọ́ Loveworld.

Moses Bliss bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin ní ọdún 2017 pẹ̀lú akọrin àkọ́kọ́ “E No Dey Fall My Hand”. Ní ọdún 2019, ó ṣe ìfìlọ́lẹ̀ orin 'Olododo' àti pé ó si tọọ ní ọdún 2020 pẹ̀lú ọkan 'Bigger Lojoojumọ'. Awo-orin akọkọ rẹ “Olododo Ju” ti tu silẹ ni Oṣu Karun ọdun 2021 ati pe o ni awọn orin 13 pẹlu “Itọju Itọju”, “Pipe” ati “E No Dey Fall Hand Mi”. Ni Oṣu Keji ọdun 2023, o ṣe ifilọlẹ awo-orin keji rẹ ti akole “Die Ju Orin lọ (Ijọsin Ikọja”, pẹlu awọn orin 13 ninu.

Àwọn itọ́kasí


Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Moses Bliss (akọrin) by Wikipedia (Historical)


Pius Adesanmi


Pius Adesanmi


Pius Adesanmi(Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ́n, Oṣù kejì, ọdun 1972 sí Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù kẹ̀ta, ọdun 2019) jẹ́ ọmọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí ó fi ìlú Canada ṣe ibùgbé. Ọ̀jọ̀gbọ́n, òǹkọ̀wé, Onísẹ́ lámèyítọ́ alátinúdá ni, òǹkọ̀wé afẹ̀dáṣẹ̀fẹ̀ àti òǹkọ̀wé sínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà. Òun ni òǹkọ̀wé ìwé Naija no dey carry last, Àkójọpọ̀ àwọn àròkọ ìfẹ̀dásẹ̀fẹ̀ ọdún 2015. Adesanmi pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ọjọ́ kẹwàá, Oṣù Kẹta, Ọdún 2019 nínú ọkọ̀ bàlúù Ethiopian Airlines Flights tí ó jábọ̀ ní kété tí ó gbéra.

Ìtàn ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

Ọmọ bíbí Ìlú Isanlu ní Ìjọba ìbílẹ̀ Apá Ìlá Oòrùn Yagba ní Ìpínlẹ̀ Kogi, Nàìjíríà ni Adesanmi. Ó gba oyè àkọ́kọ́ nínú imọ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀dá (BA.)nínú Èdè Faransé ní Yunifásítì ti Ìlọrin ní ọdún 1992, oyè ìjìnlẹ̀ (MA)nínú Èdè Faransé ní Yunifásítì ti Ìbàdàn ní ọdún 1998, àti oyè ìjìnlẹ̀ gíga nínú Èkọ́ Faransé ní Yunifásítì ti Bìrìtìkó, Columbia, Canada ní ọdún 2002

Ìṣẹ́

Adesanmi di ọmọ ẹgbẹ́ Ibùdó Ìmọ̀ èdè Faransé fún ìṣèwádìí ní Áfíríkà (French Institute for Research in Africa -  IFRA) ní Ọdún 1993 sí ọdún 1997, and Ibùdó Ìmọ̀ Èdè Faransé ni Ìlú Apá Gúúsù Áfíríkà (South Africa) ní ọdún 1998 sí 2000. Ó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú imọ̀ Lítíréṣọ̀ Ìfarawéra ni Yunifasiti ìjọba Ìpínlẹ̀ Pennsylvania, USA láàrin ọdún 2002 sí 2005. Ní ọdún 2006, ó darapọ̀ mọ́ Yunifásítì Carleton gẹ́gẹ́ bí i Ọ̀jọ̀gbọ́n Lítíréṣọ̀ àti Èkọ́ ajẹmọ́ Áfríkà. Òun ni olùdarí ibùdó ìmọ̀ Yunifásítì ti Èkọ́ Ajẹmọ́ Áfíríkà kí ó tó di olóògbé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Adesanmi jẹ́ òǹkọ̀wé tó ń kọ àwọn èrò rẹ̀ sínú ìwé ìròyìn premium Times àti Sahara reporters lóòrèkóòrè. Ìfẹ̀dásẹ̀fẹ̀ ló pọ̀jù nínú àwọn àròkọ rẹ̀, ó ṣe átẹnumọ́ alákiyèsí lórí àwọn ohun kòbọ́gbónmu tí ó ṣẹlẹ̀ ni agbo òṣèlú àti ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àwọn ẹ̀dá tó ṣàyàn láti máa kọ èrò rẹ̀ lè lórí  ni àwọn olóṣèlú, àwọn pásítọ́ àti àwọn gbajúmọ̀ àwùjọ tí ó ṣe pàtàkì. Ní Oṣù Ọ̀wàrà, ọdún 2015, ó ṣọ̀rọ̀ lòdì sí ìgbésẹ̀ Emir tí Kano tẹ́lẹ̀ rí Lamido Sanusi láti gbé ọmọdé ní ìyàwó di kókó ọ̀rọ̀, kódà Emir fún lésì lórí ọ̀rọ̀ náà. Ní ọdún 2015, ó ṣọ̀rọ̀ lórí TED Talk tí àkòrí ń jẹ́ "Ìlú Áfíríkà ní I Ìtẹ̀síwájú tí àgbáyé ni láti gbajúmọ̀.

Ikú ati ìyẹ́sí rẹ̀

Adesanmi kú ní ọjọ́ kẹwàá, Oṣù Ẹ̀rẹnà, Ọdún 2019 nígbà tí bàlúù Ethiopian Airlines Flights 302 jábọ̀ ní kété tí ó gbéra láti Addis Ababa sí Nairobi. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn Òǹkọ̀wé káàkiri àgbáyé kọ àkójọpọ̀ ewì ọ̀tàlélúgbaléméje tí wọ́n pè ní (Wreaths for a Wayfarer) ní ìtọ́kasí sí ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó tẹ̀ jáde ní ọdún 2001. Daraja Press ló gbé jáde láti fi ṣe ìyẹ́sí rẹ̀. Nduka Otiono àti Uche Peter Umezurike ni wọ́n ṣiṣẹ́ olótùú Àkópọjọ̀ ewì náà

Àkójọpọ̀ àwọn ìwé tí ó kọ

The Wayfarer and Other Poems (Oracle Books, Lagos; 2001)

You're Not a Country, Africa (Penguin Books; 2011)

Naija No Dey Carry Last (Parrésia Publishers; 2015)

Who Owns the Problem? Africa and the Struggle for Agency (Michigan State University Press; 2020).

Àwọn àmì-ẹyẹ tí ó gbà

Ní 2001, Ìwé Adesanmi's àkọ́kọ́ The Wayfarer and Other Poems, gba àmì ẹ̀yẹ ewì Ẹgbẹ́ àwọn Òǹkọ̀wé Orílẹ̀èdè Nàìjíríà (Association of Nigerian Authors' Poetry Prize).

Ní 2010, Ìwé rẹ̀ You're not a Country, Africa (Penguin Books, 2011), Àkójọpọ̀ àròkọ, gbégvá orókè níbi ìfilọ́lẹ̀ Penguin Prize fún African Writing in the nonfiction category.

Ní 2017 Adesanmi ni ó gbà Canada Bureau of International Education Leadership Award..

Giuseppe Zanotti Luxury Sneakers

Àwọn Ìtọ́kasí


Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Pius Adesanmi by Wikipedia (Historical)


Eedris Abdulkareem


Eedris Abdulkareem


Eedris Turayo Abdulkareem Ajenifuja (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kejìlá, ọdún 1974) tí gbogbo ayé mọ̀ sí Eedris Abdulkareem, jẹ́ olórin ilẹ̀ Naijiria tó máa ń kọ orin hip-hop, RnB àti Afrobeat, ó tún máa ń kọ orin kalẹ̀.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

Ìdíle olórogún ni a bí Eedris Turayo Abdulkareem Ajenifuja sí ní ìpínlẹ̀ Kano, ní orílẹ̀-èdè Naijiria. Ìlú Ilesha, ní ipinle Osun ni bàbá rẹ̀ ti wá, ìyá rẹ̀ sì wá láti ipinle Ogun, tí ó wà ní apá Gúúsù ilẹ̀ Naijiria, àmọ́ ó yan Ipinle Kano gẹ́gé bíi ìlú tó ti wá.

Àtòjọ orin rẹ̀

Studio albums

  • P.A.S.S (2002)
  • Mr. Lecturer (2002)
  • Jaga Jaga (2004)
  • Letter to Mr. President (2005)
  • King Is Back (2007)
  • Unfinished Business (2010)'
  • Nothing But The Truth (2020)

Singles

  • "Jaga Jaga part 2" (2012)
  • "Wonkere ft Fatai rolling dollar" (2011)
  • "Sekere" ft Vector (2013)
  • "Fela ft Femi Kuti" (2013)
  • "I Go Whoze You ft Vtek" (2013)
  • "Trouble Dey Sleep" ft Konga (2016)̀
  • "Jaga Jaga Reloaded" (2021)
  • "Oti Get E" (2021)

Àwọn ìtọ́kasí


Text submitted to CC-BY-SA license. Source: Eedris Abdulkareem by Wikipedia (Historical)






Text submitted to CC-BY-SA license. Source: by Wikipedia (Historical)






Text submitted to CC-BY-SA license. Source: by Wikipedia (Historical)






Text submitted to CC-BY-SA license. Source: by Wikipedia (Historical)






Text submitted to CC-BY-SA license. Source: by Wikipedia (Historical)